ÌPÈSÈ AWỌN OHUN IDERUN: ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ GÉ IYE OWÓ OKÒ SÍ IKO MEEDOGBON NÍNÚ ÌDÁ ỌGỌRUN

ÌPÈSÈ AWỌN OHUN IDERUN: ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ GÉ IYE OWÓ OKÒ SÍ IKO MEEDOGBON NÍNÚ ÌDÁ ỌGỌRUN

... Bẹrẹ ètò fífún Eedegbejo awọn aráàlú l'ounjẹ l'ojumo L'awon Ìjọba Ìbílè nípasẹ Ilé Ìdáná ọbẹ sise

... Bẹrẹ ètò pínpín awọn ohun iderun tí yóò dele-d'oko láì yọ awọn aráàlú atawon Ilé -Ise Àdáni silẹ

Lára àwọn ètò mímú iderun b'awọn aráàlú latari ojojo tó deba ètò ọrọ Ajé tawon Olùgbé Ìpínlè Èkó si mo lára, èyí ló jẹ́ kí Gómìnà Babajide Sanwó-Olu mú adinku bá Iye owó ọkọ, nípasẹ yíyọ ikò Meedogbon nínú ida ogorun owó ọkọ tawon aráàlú n wò, N'ipinle Yìí.

Gómìnà Sanwó-Olu sọrọ yìí lásìkò tí wọn fikunlukun pẹlu awọn Akoroyin, èyí tí Àkòrí rẹ jẹ, " Ìpèsè Oúnjẹ l'ọpọ yanturu" Yorùbá bọ, wọn ní B'ounje bá ti kúrò nínú ise, iṣẹ buse, woye pé, Ìjọba kò lè da gbogbo ẹrù náà gbé, wọn kò tún ní lè wà níbi gbogbo lẹkan náà, ìgbésẹ akin tí wọn gbé náà, yóò gbé eru kúrò l'orun àwọn Olùgbé Ìpínlè yìí , torí pé, ipenija ti wón n doju kọ pọju, lásìkò yìí.

Gómìnà Sanwó-Olu sọ pé, " l'akoko náà, o yẹ ki wọn kí àwọn aráàlú kú iroju náà. Irọ la pa, tí a bá sọ pé, a kò mọ ohun tó n ṣẹlẹ. Mo fe mú ojú Ajé ko oniso bayii pé, a gbọ́dọ̀ ṣe ojúṣe wa dáadáa. Bí Asaaju gidi kò yẹ kí a máa wá awawi rárá, bíkòṣe pé kí, a wá ojútùú sọrọ ètò ọrọ Ajé tó denukole yìí f'awon aráàlú".

O Ṣàlàyé pé, ìṣàkóso Ìjọba òun yóò pèsè ounjẹ iderun f'awon Olùgbé Ìpínlè yìí, bákan náà, Gómìnà jẹ kí o di mimọ fún wa pé, ọgọrun ọkọ Tirela ló n ko Iresi bọ wá S'ipinle Èkó báyìí, gbogbo Olùgbé Ìpínlè yìí tí wọn lé ní Egberun l'ọna Oodunrun ni wọn yóò J'anfaani lásìkò pínpín awọn oúnjẹ náà.

Gómìnà sọ pé, awọn ohun iderun T'isakoso Ìjọba òun yóò pin yóò d'ele-d'oko láì yọ ẹnikẹ́ni silẹ, kódà, awọn Ilé -Ise Àdáni náà yóò j'anfaani níbè, àti pé, ìgbésẹ akọkọ ni yiyọ iko Mẹẹdogbon nínú ida ogorun iye owó ọkọ tí wọn n wọ kúrò, ibẹrẹ ètò ìpèsè oúnjẹ sise l'awon ilé Ìdáná Káàkiri gbogbo àwọn Ìjọba Ìbílè Metadinlọgofa tí wọn wà N'ipinle Yìí, O kéré tán, Ẹgbẹrun kan sí Eedegbejo Olùgbé Ìpínlè yìí ni wọn yóò máa jẹun níbè l'ofee, l'ojumo.

Ọgbẹni Gómìnà tún yanana rẹ pé, Ìṣàkóso Ìjọba òun tún n ṣètò Ọjà Mejilelogoji tí wọn yóò máa ná lójó Àìkú nìkan, níbi t'awọn aráàlú yóò ti lọ máa ra ounjẹ l'ówó pooku, gbogbo àwọn ohun t'awọn aráàlú yóò máa rà níbè kò ní ju Egberun Meedogbon Náírà lọ. O Ṣàlàyé pé, irú ojà béè ni, wọn ṣí sí Àgbègbè Ìdí Oro, tawon Oṣiṣẹ Ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó n b'awọn Oṣiṣẹ Ìjọba Ìbílè atawon Asaaju àwọn Ọjà náà sise, K'aje lè máa bu igba jẹ l'awon Ọjà náà.

Olùdarí Gbogbogboo Ìpínlè yìí sọ pé, tí wọn bá fẹ S'aseyori níbè, awọn oṣiṣẹ Ọba onipele Kínní dé ìpele Kẹrinla yóò lọ máa sisé l'ọja náà l'eemeta láàrin ose , béè sì ni, awọn oga wọn yóò lọ máa sisé níbẹ l'eemerin láàrin ose. O tẹnumọ pé, Ìjọba Ìpínlẹ̀ yìí ṣetan àti S'atileyin fawon Olukọ torí pé, Eemarun ní wón yóò máa lọ síbi isé láàrin ose, béè sì ni, awọn oṣiṣẹ Ìlera yóò sì máa bá iṣẹ tetete tí wọn ṣe ló.

O kéde pé, Ìṣàkóso Ìjọba òun yóò gbé ìgbìmò Alabesekele l'órí ọ̀rọ̀ ètò Ajé kalè, tí wọn yóò máa jiroro pẹlu l'ọna tí o yẹ ki wọn gbà, Gómìnà wá kéde pé, láti isinsin yìí lọ, ọfẹ l'awọn Aláboyún yóò máa b'imo l'awọn Ile-iwosan Ìjọba, I baà jẹ ọmọ tí wọn bí woorowo tàbí èyí tí wọn ṣíṣe abẹ fún kí o tó lè b'imo.

O Ṣàlàyé pé, ọpọ awọn Olùgbé Ìpínlè Èkó ló jẹ pé ètò Ìlera tó péye ni wọn nilo kìí ṣe oúnjẹ rárá, Gómìnà Ṣàlàyé pé, ètò Ìlera ọfẹ yóò tó bẹrẹ, tí wọn yóò máa ṣe ayẹwo ọfẹ àti ìpèsè Egboogi Òyìnbó lófèé káàkiri ẹkùn Mefeefa tí wọn wà N'ipinle Yìí, béè sì ni, awọn akosemose eleto Ìlera ní yóò máa Ṣ'ayẹwo fún wọn t'eto náà bá bẹrẹ ní pereu.

Gómìnà rawọ ebe s'awọn onisowo keekeekee pé kí wọ́n f'owo Okunkundun mú iṣẹ wọn, kí wọn tún fí ìwà Omoluabi kún, torí pé, àkókò tí a wà nisinyii kìí ṣe nípa èrè tí wọn fẹ jẹ, bíkòṣe pé, kí wọ́n mojuto awọn omolakeji wọn.

"A ṣe nigba Àjàkálẹ̀ Ààrùn COVID-19. A huwa Omoluabi nígbà náà. A S'atileyin fún ara wa. Àkókò tó láti so'wopo papọ titi tí gbogbo nnkan tó n run n'ile yóò fi tán. Fún ìgbà díe ní, gbogbo nnkan tí a n là kọjá yìí, yóò di afiseyin t'eegun n fi aṣọ ", Gómìnà gba awọn aráàlú l'amoran yìí.

Awọn Akoroyin tí wọn dá-n-to l'ẹnu ìgbín ní wón S'agbateru ètò ifikunlukun pèlú àwon Oniroyin náà, awọn Akoroyin bíi, Reuben Abati Ilé -Ise Telifisan Arise, Ṣọla Kosoko, Ilé -Ise Telifisan LTV, Babajide Otitoloju láti Ilé -Ise Telifisan TVC àti Jeffery Uzomma, láti Ilé -Ise Telifisan Channels. Awọn èèyàn jankan-jankan ti wón wà níbí apero náà ni, Igbakeji Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, Omowe Kadri Obafemi Hamzat, awọn ìgbìmò aláṣẹ Ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó, awọn Akoroyin kọọkan, awọn oniṣowo kọọkan, at'awọn èèyàn miiran.

#AGreaterLagosRising
#LASG

Comments

Popular posts from this blog

CELEBRATING THE EXTRAORDINARY LEADERSHIP OF AARE OLANREWAJU MICHAEL GEORGE (OMG) -Olumide Adebayo (McAnelka)

HON. OGUNLEYE COMMISSIONS LANDMARK PROJECTS IN IKENNE LOCAL GOVERNMENT

IKENNE LOCAL GOVERNMENT BOSS CONGRATULATE ALHAJI APELOGUN ON HIS RE-ELECTION