ÈMI AISHA YESUFU, OLÓṢÈLÚ NI MÍ. - NEIGHBORHOODMEDIA

Breaking

Wednesday, March 6, 2024

ÈMI AISHA YESUFU, OLÓṢÈLÚ NI MÍ.

Nínú fanran kan ti gbajú-gbajà Ajafeto omo eniyan Aisha Yesufu fi sita lori òpó YouTube re loti se alaye lekun rere ìdí ti gbogbo eniyan fi gbodo kopa nínú ètò Oṣelu. Nínú oro re, o ni;

"Mokí gbogbo eyin èèyàn patapata. Mo ní kin so fun yi tí e o ba mo tele, wípé olòsèlú ni mi. Beeni, e gbó mi dada, OLÒSÈLÚ NI MI."

Se e ri àwon àìlóyè to lori òrò oselu, ti a n so wipe; emi o, emi kìn se olòsèlú, mi o se oṣelu, mi o se eleyi, mi o se tòhún. Nísìyí, Olòsèlú ni mi.

Saaju ni Mo wa Lori ètò kan, eyi ti o je ìdí Pataki ti mo se fi atejise kan sita lori òpó X (Twitter). Ojogbon Kingsley Moghalu lo je agbọrọsọ agba lori Eto naa, nínú oro re, o so wipe lóòtóó ni ohun jade du ipo nínú ìdíje oṣelu to kojá, sugbon ohun kii se olòsèlú.

Láti odun 2018 ni moti mọ wipe o je iwa agò láti duro si egbe kan, ka so wipe a o fe k'opa nínú oro oṣelu, eyi to je wipe àwon alailoye a bo si ipo ase tan, a o wa jade sita maa paruwo láti fi ehonu wa han. Fi ehonu han si àwon wo? Àwon ti o setan láti teti sile si wa.

Leyin Ìgbà ti won bura wole ni ònà aito fun Are to wa ní ijoba, àwon kan beere lowo mi wipe se maa te siwaju láti maa bere ètó lowo ijoba. Mo ní èmi! Beere eto lowo eni tí o 'dangajia'. Mo ni rara o, ise kan soso tí mo ní bayi ni kin ri wipe Mo kin àwon èèyàn to kun ojuwon leyin láti wo inu oṣelu ati kin ri daju wipe won dije, won si wole.

Fun emi o, ise takuntakun lo je mi logun. Saaju loju òpó X (Twitter), òrò tí mo fi sita ree;  

"Oloṣelu ni mi. Ni gbogbo igbesi aye mi ni mo ti ní awọn aṣayan.
 Mo wa sinu oselu Naijiria, ní abé iṣọ mi ati ni awọn aaye ibi ti mo ti ṣiṣẹ, èmi yoo rii daju pe o mọ.
 
Òrò-kọrò itiju tàbí àbámò nípa oselu, ka mi jade. Ti o ba sọ pe oṣelu Naijiria jẹ ìdíje idoti, dide kí o múra ní gírí, jẹ ki a sọ di mimọ. 

Àìse ohunkóhun kò lè yanjú ohunkohun. Iseda korira igbale. Ti o ba lọ kuro nínú ìsèlú Naijiria, awọn miiran yoo gba aaye naa, won a sì ṣe awọn ipinnu fun ọ". 

Oṣelu ni kí a joko láti se ipinu irúfé èèyàn ti a fe ko je Olori wa. Ti won ba sọ pe oṣelu jẹ ìdíje idoti, e je ki a dide, ka ri aridaju wipe a sọ di mimọ. Ti won ba n se ipade ni agogo meji Oru, to je ìdí ti orílè-èdè Naijiria o fi te siwaju, e je ki a gbe ipade naa wa so agogo meji osan.

E je kia ri wipe àwon to ni ise lowo, to ni òwò kan tàbí òmíràn ti won n se ni a ti leyin láti de ipo ase, kii se àwon ti o gbé gbogbo bukata atije won Lori oṣelu. Kii se ìdíje bo ba opa, boo ba o bu lese la n se.

Nígbà kan rí ní orílè-èdè yi, bi Are Naijiria ba gbà egbe mi kojá, o seese kin ma damò, nitori, igbagbo mi ni wipe mi o ni ohun kankan láti se pèlú àwon to wa nipo ase. Mo kanju mo ise mi ni. Sugbon sa, nísìyí, mo ti wa rii wipe àwon to n wo ilu oṣelu lo ló wà n dari ise mi ti Mo kanju mo nípa àwon àlàkalè ètò ìmúlò won. Fun idi eyi, mi ni láti ri daju wipe Mo f'oju si àwon Ilana naa.

Bi mo ba f'oju si àwon Ilana yìí, ko ni je ojuse mi láti maa san Owó ilé iwe àwon kan, ko ni je ojuse mi láti maa san Owó ilé iwosan àwon kan tàbí láti maa wa ounje fun àwon kan. Mi o Fe ki awon èèyàn nílò mi rara àti rara, nitori ti a ba ni ijoba to dara, to n jiyin fun ara ilu, ti idagbasoke wa, ti a ni ise lowo, ti Eto oro aje n lo déédé, àwon eniyan o ni nilo iranlowo mi, won a le tanju arawon, won a sì le gbe igbe aye to wu won. Ohun tí mo fe niyi.

ÀÌLÓYÈTÓ NÍPA ÒṢÈLÚ.

Lori òpó X (Twitter) mi ni odun 2021, mo fi atejise sita gégé bí ojogbon Bertolt Brecht se se akosile re;

"Awọn alailoye ti o buru ju ni awọn alailoye oloselu, ko gbọ, ko sọrọ, tabi kopa ninu awọn iṣẹlẹ oselu. Ko mọ iye owo igbesi aye, iye owo ewa, ti ẹja, ti iyẹfun, iye Owo igbe, ti bata ati ti oogun, gbogbo rẹ da lori awọn ipinnu oselu. Òmùgọ̀ alailoye òṣèlú tí ó máa ń gbéra ga, a tun maa f'owo lu àyà ara rẹ̀ pé òun kórìíra òṣèlú. Alaiṣedeede ko mọ pe, lati inu aimọ oselu rẹ ni a bi panṣaga, ọmọ ti a kọ silẹ, ati awọn olè ti o buru ju gbogbo lọ, oloselu buburu, ibajẹ ati aiṣan ti orilẹ-ede lapapo àti awọn ile-iṣẹ".

Ni odun 2020, nígbà tí enìkan so wipe mi kii se ololufe Eto Oṣelu, mo je ko di mimo fun wipe ó ní àse sí ona to gba láti woo, sugbon, aije ololufe Eto Oṣelu ni ìdí ti won a fii maa lo o gégé bí erú dipo bi omo onilu.

Elomiran ni odun 2020 so wipe; "ohun ri Eto Oṣelu orílè-èdè Naijiria gégé bí ohun itiju láti darapo mo, tàbí ohun amuyangan lawujo". Ti o ko ba darapo mo Eto Iṣelu Naijiria, Eto Iṣelu a darapo mo, a se àwon àlàkalè Ilana ti yio da gbogbo ònà re ru, láti Ori Eto isuna titi de Eto imayederun.

Ebi n pa àwon eniyan, àwon kan n doju ko oko ajagbe tí o ko ounje. Bawo Le se ro wipe a de ibi? ÒṢÈLÚ! Òṣèlú ni à o se láti dibo fun àwon oludari wa. Bi àwon kan ba n sa seyin ika kan wipe àwon kii se olòsèlú, èmi Aisha Yesufu, Olòsèlú ni mi, Mo ti wa nínú Oṣelu.

~Yorùbádùnñkà

No comments:

Post a Comment